KÍKỌ́ ÀTI MÍMỌ AÁYAN ÒGBUFỌ̀ LÉDÈ YORÙBÁ: ÀWỌN ÌṢÒRO TÍ Ó Ń KOJÚ RẸ̀

Main Article Content

Fatmat Àdùkẹ́ Lawal

Abstract

Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni ìjọba fọwọ́ sí láti máa ṣe aáyan ògbufọ̀ rẹ̀, pàápàá jùlọ fún àwọn àjọ WAEC, NECO ati JAMB nínú ìdánwò àṣekágbá wọn. Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni èdè tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fọwọ́ sí gẹ́gẹ́ bí èdè àmúlò gbogboogbò fún ìbá-ara-ẹni-sọ̀rọ̀ níbikíbi. Ìdí nìyí tí àwọn àyọkà tí á máa ń fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti túmọ̀ sí èdè Yorùbá fi máa ń jẹ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Onírúurú ìwé ìròyìn ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ni àwọn oníròyìn máa ń tú sí èdè Yorùbá ní ilé-iṣẹ́ rédíò àti amóhùn-máwòrán. A máa ń rí àwọn ògbufọ̀ tí wọ́n máa ń túmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ilé ìjọsìn, ìgbéríko tàbí níbikíbi tí wọ́n ò bá ti gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì yálà ní kíkọ sílẹ̀ tàbí ní sísọ lẹ́nu. Bí aáyan ògbufọ̀ yìí ṣe ṣe é fẹ̀mìí tẹ̀ tó, síbẹ̀ ó ṣeni láànú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé-ìwé wa kò kọbi ara sí kíkọ́ àti mímọ̀ rẹ̀ tó bí ó ti yẹ. Nítorí náà, iṣẹ́ yìí yóò ran olùkọ́, akẹ́kọ̀ọ́, àwùjọ àti ìdàgbàsókè èdè lọ́wọ́, tí èróńgbà lórí aáyan ògbufọ̀ yóò sì di mímúṣẹ. Ìdí nìyìí tí iṣẹ́ yìí yóò ṣe wo ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ohun tí a le pè ní aáyan ògbufọ̀ ọlọ́kan-ò-jọ̀kan. A ó tún tẹ̀ síwájú láti wo àwọn ìlànà tí ó ṣe kókó tí a gbọdọ̀ tẹ̀lé kí á tó saáyan ògbufọ̀ tàbí nígbà tí a bá ń saáyan ògbufọ̀ lọ́wọ́. A ò ní ṣàì ṣe onírúurú àpẹẹrẹ aáyan ògbufọ̀ nípa ṣíṣe àmúlò tíọ́rì ìfojú ìtumọ̀ wo àṣà, ọrọ̀ ajé, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ abbl. A ó wo sàkun àwọn ohun tí ó ṣe é ṣe kí ó jẹ́ ìṣòro tí ó ń kojú aáyan ògbufọ̀ kí á tó wá ṣakitiyan láti wo èrèdí aáyan ògbufọ̀ àti ìwúlò wọn láwùjọ látàrí àti lè mú ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè bá aáyan ògbufọ̀ ṣíṣe ní àwọn ilé ìwé wa gbogbo.

Article Details

How to Cite
Lawal, F. A. (2024). KÍKỌ́ ÀTI MÍMỌ AÁYAN ÒGBUFỌ̀ LÉDÈ YORÙBÁ: ÀWỌN ÌṢÒRO TÍ Ó Ń KOJÚ RẸ̀. Journal of Nigeria Languages’ Studies (NILAS), 4(2), 66–76. Retrieved from https://nilas.com.ng/index.php/nilas/article/view/43
Section
Articles